HYMN 668

C.M. (FE 694)
“lfe lo ye omo enia."1. B’OKIKI ija tile nkan 

   T’ariwo gb’ode kan 

   K’irepo wa n’ile dara 

   Omo Iya ki ja.


2. Awon eiye n’nu ite won 

   Ki ba ara won ja 

   Ohun itiju nla ha ko 

   K’omo-ya ka repo.


3. Ihale-ako-apara

   Fari lasan lasan

   Kumo ni da, a fa da yo 

   A si bi ‘ku l’omo.


4. lse bilisi n’ibinu 

   Larin omo iya 

   Ibinu ni Kaini fi Iu 

   Arakunrin re pa.


5. Ibinu ologbon ki pe

   A tan k’orun to wo 

   Sugbon t’asiwere a wa 

   Titi d’ojo ale.


6. Fi ese inu-bibi wa

   Ji wa, Oluwa wa

   Ka f’ibinu ewe sile 

   Ka si dagba n’ife. Amin

English »

Update Hymn