HYMN 67

(FE 85)
"Oba Oludariji, dariji wa"1. JESU Oba ogo dariji wa,

   Wo wa san ninu arun ese gbogbo

   ‘Wo to wo awon adete gbani san

   Jowo masai wo aisan wa gbogbo san.

Egbe: Wole, wole, wole w'odu Jesu

      Wole wa, wole, iwo yio gb’ade,

      A mo daju p’awa yio de Kenian

      Nibiti Baba wa ti pese fun wa.


2. Olorun Abram ati Isaaki

   Olorun Jakob jowo dabobo wa,

   Jowo mu ona wa to niwaju Re,

   Ko si ranti gbogbo wa si rere.

Egbe: Wole, wole...


3. lwo to wa pelu Sedrak Mesak

   Abedinigo ninu ina ileru

  Jowo yo wa ninu idekun esu

  Ka le b'awon Angel korin loke.

Egbe: Wole, wole...


4. Ogo fun Baba, Omo at’Emi

   To da emi wa si di ojo oni,

   Jowo ran oluranlowo Re si wa

   Ki ‘segun je tiwa lat’ oni lo.

Egbe: Wole, wole... Amin

English »

Update Hymn