HYMN 672

C.M. (FE 698)
“Bi enikan ko ba sise ninu oro, on
na li eni pipe.” - Jak.3:2 
“Ifi enia se esin, ese nla ni.”1. FUN iyin Olodumare

   L’a s’eda ahon wa 

   B’awon kan tile kegan wa 

   K’a s’adura fun won.


2. Ifi’ni s’esin eleya 

   Ko to n’ile-iwe

   K’a si p’enia ni were 

   S’ewu iparun ni.


3. Enikeni t’o wu k’ose

   Ti ba nso ‘sokuso

   S’awon mimo s’ohun mimo 

   L’Oluwa y’o lu pa.


4. Gbat’awon ‘mo buburu ni 

   Nfi Elisa s’esin

   Ti nwon nkigbe soke, wipe 

   Goke lo, wo pari.


5. Logan k’Olorun lu won pa 

   T'o ran beari meji

   T'o fa won ya perepere 

   Titi nwon fi ke ku.


6. Ibinu Re ti I'eru to! 

   S’awon omo-komo

   Fi ore-ofe Re, Baba 

   K'ahon mi n'ijanu. Amin

English »

Update Hymn