HYMN 679

L.M (FE 704)
“Igberaga aso wiwo irera ati ogo asan, 
ese nla ni."1. K’IYA wa, Efa to d’ese 

   Tal’ o mo ohun ti nje aso?

   Ohun ta fi bo l’asiri 

   Pada d‘ohun irira re.


2. Gbat‘ o ko gb’ewe opoto wo 

   Oso iwa mimo re lo

   Sa wo bi awa omo re

   Ti nf’ibo tiju yi sogo.


3. Wo! b’igberaga wa ti to 

   Gbat’ a ba gb’aso titun wo 

   B’enipe awon kokoro

   At’ agutan ko ti nwo won.


4. Wo arewa labalaba 

   Ali itanna pulpit

   B’aso mi ti wu ko po to 

   Ko t’abo ti awon wonyi.


5. Nje ngo ma fi okan mi wa 

   Ohun oso t'oju won lo

   lwa rere at’otito

   L’oso to ju gbogb’oso lo.


6. Nigbana l’emi y’o dara 

   Pupo j'awon kokoro lo 

   Oso awon angel l’eyi 

   Ati t‘Om‘Olorun pelu.


7. Ki ti, ki gbo, ki sa titi 

   lpara ko si le baje

   T’ojo t’erun, bakanna ni 

   Lilo ki ba ewa re je.


8. Eyi ngo ma wo laiye

   Ki nle ma wo l’orun pelu 

   Oso t‘o w‘Olorun l’eyi 

   Ogo ati ayo Re ni. Amin

English »

Update Hymn