HYMN 681

10s (FE 706)
"Wo iya re" - John 19:27 
Tune: Wa ba mi gbe ale fere le1. ORUKO wo lo dun gbo bi t‘iya 

   Ti eti ngbo ti okan si bale 

   Adun t’ enu ko le so miran wo 

   Ninu oruko rere bi t’iya.


2. A! iya ti ngba ya omo re je

   A! iya ti ngbekun omo re sun 

   A! iya ti npebi monu f’omo

  Mo fe o nigbagbogbo iya owon.


3. Jowo ran mi Iowo, Edumare

   K'emi Ie toju awon obi mi 

   Fun mi layo pupo nigb'aiye mi 

   Ki nma sanku mo obi mi Ioju.


4. Agborandun bi iya ko si

   Eni to ni baba Io tara re

   Bi ina ku a fi eru boju

   Iya mi ti fi mi ropo’ra re. Amin

English »

Update Hymn