HYMN 683

ADURA FUN AWON OBI
(FE 708) C.M.S. 397 t. H.C 34 C.M
"To omode l’ona ti yio to" - Owe 22:61. OLORUN ogbon at’ore 

   Tan ‘mole at’oto

   Lati f'ona toto han wa 

   Lai to 'sise wa.


2. Lati to wa ninu ewu

   Li arin apata

   Lati ma rin lo larin won 

   K'a m’oko wa gunle.


3. B’or'ofe Re ti nmu wa ye 

   K’a ko won b'eko Re 

   Awa lati ko omo wa

   Ni gbogbo ona Re.


4. Li akoko, pa ife won

   On ‘gberaga won run! 

   K'a ti ona mimo han won 

   Si Olugbala won.


5. A fe woke nigbakugba 

   K'a to apere Re

   K‘a ru beru on ‘reti won 

   K'a tun ero won se.


6. A fe ro won lati gbagbo 

   Ki nwon f’itara han

   Ki a mase lo ikanra 

   Gbat' a ba le lo ‘fe.


7. Eyi l’a f'igbagbo bere 

   Ogbon t’o t'oke wa!

   K’a f’eru omo s’aiya won, 

   Pelu ife mimo.


8. K'a so ‘fe won ti nte s’ibi 

   Kuro l'ona ewu

   K‘a fi pele te okan won 

   K'a fa won t’Olorun. Amin

English »

Update Hymn