HYMN 688

C.M. (FE 713)
"Oluwa, ko mi Ii ona Re, emi o 
si ma pa mo de opin" - Ps. 119:33
“Apere Olorun mimo lati igba ewe.”1. WO awon apere wonni 

   Ti mbe n’nu Bibeli 

   T’awon t’o fe Isin Jesu 

   Lati ‘gba ewe won.


2. Jesu, Oba l’oke orun 

   T‘ola Re kun aiye 

   Je omode bi emi ri

   O np’ ofin baba mo.


3. Mejila pere l‘odun Re 

   Gb‘o ndamu awon Ju 

   Sugbon sibe, o teriba 

   O si gbo t’iya Re.


4. B'awon agba ti nkegan to 

   Ti nwon ns’abuku Re

   Be l‘awon ewe nyin logo 

   Ti nwon nke Hosanna!


5. Bi Samueli, Timoti 

   Lat” igba ewe won

   Ti nf’ itara sin Oluwa 

   Be l'o ye ki nma se.


6. Ko to ki nf’ isin Oluwa 

   Se jafara rara

   Ki y’o di ola ki nto bere 

   Si ise rere yi. Amin

English »

Update Hymn