HYMN 691

C.M.S 576 H.C 378 6s 4s (FE 716) 
"Ibukun ni fun awon ti ngbe inu ile Re."
- Ps. 84 : 41. KRISTI n’ipile wa 
 
   Lori Re lao kole 

   Awon Mimo nikan 

   L’o ngb’ agbala orun

   Ireti wa, T'ore aiye

   T’ayo ti mbo, Wa n‘nu fe Re.


2. Agbala Mimo yi 

   Y’o ho f’orin iyin 

   A o korin iyin si 

  Metalokan Mimo,

  Be lao f’orin, Ayo kede 

  Oruko Re, Titi aiye.


3. Olorun Olore 

   Fiyesini, nihin 

   Lati gba eje wa 

   At’ebe wa gbogbo

   K‘o si f’opo, Bukun dahun, 

   Adura wa, Nigbagbogbo.


4. Nihin, je k’ore Re 

   T’a ntoro l’ at’orun 

   Bo sori wa lekan 
 
   K’o ma si tun lo mo

   Tit’ojo na, T‘ao s‘akojo 

   Awon Mimo Sib’isimi. Amin

English »

Update Hymn