HYMN 693

C.M.S 575 K. 454 t.H.C
"Jeki oju Re siu si ile yi Ii osan ati
Ii oru.." - 1Oba 8:291. A FI ipile yi le le

   Ni oruko Re Oluwa

   Awa mbe O Oluwa wa, wa 

   Ma toju ibi mimo yi.


2. Gba enia re ba nwa O 

   T'elese nwa, O n‘ile yi 

   Gbo, Olorun, lat’ orun wa 

   F'ese ji won, Olorun.


3. Gb‘awon Alufa ba nwasu 

   lhinrere ti Omo Re,

   Ni oruko Re, Oluwa

   Ma sise iyanu nla re.


4. Gb'awon omode ba si nko 

   Hosannah si Oba won

   Ki Angeli ba won ko pelu 

   K'orun at’aiye jo gherin.


5. Jehovah, o ha ba ni gbe 

   Ni aiye buburu wa yi 

   Jesu, o ha je Oba wa 

   Emi o ha simi nihin?


6. Ma je ki ogo re kuro

   Ninu ile ti a nko yi 

   Se ‘joba Re ni okan wa,

   Si te ite Re sinu wa. Amin

English »

Update Hymn