HYMN 697

H.C 513 8.9.8.8 (FE 722)
“Jeki oju Re si si ile yi”
- 1Oba 8:29
Tune: A nsoro ile bukun ni1. NIHIN l‘oruko Re Oluwa 

   A ko le erupe fun O

  Yan fun ‘bugbe Re pataki 

  K'o si so lowo ja esu.


2. Gbati a ba ngbadura nihin 

   T’elese nbebe fun Iye 

   Gbo lati 'bugbe re orun 

   Gbat' o ba gbo k‘o dariji.


3. Gbat;’ a nwasu Re nihin 

   Ninu ile Mimo Re yi 

   Nip‘ agbara Oko nla Re 

   K‘ise yanu re farahan.


4. Gbat' awon ewe ba nkorin 

   Hosanna si Oba wa loke

   Ki ogo Re kun ile yi 

   K’Angeli ba won korin na.


5. K'ogo Re ma gbe ile yi 

   Yan ni ile patapata

   Te ite Re sinu ‘le yi 

   Majeki esu le wo ‘be.


6. Jah Jehofa, Oba Mimo 

   Sokale sinu okan wa

   Ma ba wa gbe inu ile wa 

   Mase fi wa sile lailai. Amin

English »

Update Hymn