HYMN 70

8.7 (FE 88)
"Kiyesi Emi mbo nisisyi" - Rev. 22:121. ELESE wa sodo Jesu

   Fun igbala re lofe

   On pe o ni ohun kele

   Pe omo ma sako mo.

Egbe: Kil’ ao ro! Kil' ao so?

      'Gbati Baba ba npe wa,

      Pe omo, siwo ko ma bo

      Wa jihin ise re o.


2. Elese wa sodo Jesu,

   Loni lojo igbala

   Yara ma si je ko pe ju

   lye mbe fun o loni.

Egbe: Kil’ ao ro! Kil' ao so...


3. Serafu damure giri

   Kerubu ma jafara,

   Opo okan ti se gbe lo,

   Wa, e wa s'agbo Jesu.

Egbe: Kil’ ao ro! Kil' ao so...


4. Jesu Olori Egbe wa,

   lfe Re ti sowon to,

   Ti O da Egbe yi sile

   Pe k'a le ri igbala.

Egbe: Kil’ ao ro! Kil' ao so...


5. Aje nyonu, oso nyonu

  Wa sabe abo Jesu

  Ohun ibi t’o wuk’o je

  Wa si egbe Serafu.

Egbe: Kil’ ao ro! Kil' ao so...


6. Elese ronu piwada

   Ki akoko to koja

   Ki metalokan to pe o,

   Pe wa siro ise re.

Egbe: Kil’ ao ro! Kil' ao so...


7. Ka le gbo nikehin ojo

   Pe o se omo rere

   Kerubu pelu Serafu

   Bo s’ayo Oluwa re.

Egbe: Kil’ ao ro! Kil' ao so...


8. Orin Halle Halleluya,

   L'a o ko ni'te baba

   'Wo n'iyin at’ope ye fun

   Ti t' aiye ainipekun.

Egbe: Kil’ ao ro! Kil' ao so... Amin

English »

Update Hymn