HYMN 71

CM
"Oluwa sanu fun mi” - Ps. 123:31. GBANGBA l‘oju Re Olorun

   S’Ohun gbogbo ta use,

   T'osan t'oru bakanna ni,

   L'oju Oluwa wa.


2. Ko s’ese kan ti a le da

   Ko s’oro t'a le so

   Ti ko si ninu iwe Re

   Fun iranti gbogbo.


3. Ese ole, ese iro

   Ese aiforiji

   Ese ka soro eni lehin

   Baba dariji wa.


4. Ese igberaga okan

   Ese isokuso

   Ese aini ‘gbagbo daju

   Baba dariji wa.


5. A! l'ojo nla ojo ‘dajo

   Ma je k‘oju tiwa

   T'oju gbogbo aiye yio pe

   Baha dariji wa.


6. Dariji mi Olorun mi,

   Ki nto lo laiye yi,

   Si pa gbogbo ese mi re

   Baba danriji mi. Amin

English »

Update Hymn