HYMN 713

Tune: D 7s1. GBO b'Olugbala ti wi

   Pe ise po n’nu ogba 

   Alagbase ko si to

   O mu ra fun ‘se na bi 

   Afunrugbin funrugbin 

  Oko pon, ikore de 

  Olukore mu doje 

  Lati ko 'rugbin wale.


2. Olugbala nke tantan 

   P’eyin onise dide 

   Gbe ihamora mi wo 

   Mura fun ‘se lat’oni 

   Akoko nsure tete 

  Ojo ikore de tan 

  Olukore ti se tan 

   Lati ko iti wole.


3. Wundia mewa la yan 

   Marun ko mura sile 

   Marun to ti mura tan 

   Ba Oba Ogo wole

   Lo talent ta fi fun o 

   Sise ‘ranse re loni 

   Foriti, tesiwaju

   Wo o gbade isegun.


4. Gbo ipe Olugbala 

   Wa je ‘pe na nisisyi 

   Mase f’akoko dola 

   Ojo igbala de tan 

   Ohun to npe nisisyi 

   Le dekun ipe lola 

   Se ‘pinnu rere loni 

   Ko le gba ade ogo.


5. Oluwa, Olorun jo

   Un o fi ayo jise Re 

   Fun mi ni ebun ahon 

   Ki njise na laiberu 

   Nigbayi li okan mi

   Y’o ma korin iyin pe 

   Ti Oluwa Olorun

   Ni iyin ati ogo. Amin

English »

Update Hymn