HYMN 715

S. 230 7s 6s (FE 742)
“Ma lo l'afiafia" - Luku 7:50
Tune: A roko a furugbin1. JESU Olugbala wa 

   Awa fi iyin fun O

   Fun ‘dasi ati pamo Re 

   Lori wa lat’esi

   A tun pejo loni yi 

   lati yin oruko Kristi 

   Kerubu, Serafu

   Awa ns’ajodun wa 

   L’oni niwaju Re 

   Ogo, Iyin ola ni fun 

   Metalokan Iailai.


2. Baba Mimo bukun wa 

   Ninu ajodun yi 

   Fi Emi Mimo Re fun wa 

   At’agbara Emi

   K’a le sin O ni Mimo 

   Gba wa lowo ese 

   Aiye, esu, idanwo 

   Fun wa ni isegun

   Ki ‘mole wa le ma tan 

   Bi ‘lu Iori oke

   E jek‘ajuba fun Jesu 

   Oba wa Olore.


3. Enyin Om'ogun Krsiti 

   E ku ewu odun

   E fun ipe Odagutan

   Ti baba fi fun yin 

   Enyin ti e nfi suru

   Ru agbalebu yin

   E o si joba lailai 

   Nigba ‘ponju ba tan

   Ipe ‘kehin dun tan 

   Fun ldajo aiye 

   Onidajo araiye yo 

   Ogunwa lori ‘te.


4. Opo elegbe wa ni 

   Ko ri ojo oni 

   Ninu idamu aiye yi 

   Opo ti sako lo

   Jesu npe l’ohun jeje 

   Pe “OMO’ ma sako 

   Pada omo imole 

   Sinu agbo Jesu

   E kede jake jado

   Fun awon keferi

   Pe, ojo Oluwa de tan 

   E ronupiwada.


5. Olorun ni Eleda 

   Orun ati aiye

   O nfun itanna l’awo

   O nmu irawo tan

   Iji gba ohun re gbo 

   O nbo awon eiye 

   Papa awa omo Re 

   T'o nbo lojojumo

   Ebun rere gbogbo 

   Lati orun wa ni

   A dupe lowo Olorun 

   Fun gbogbo ife Re.


6. Igba wa mbe l‘owo re 

   Nin’odun t’a wa yi 

   Om’ogun Kristi, e gbadura 

   Metalokan y’o gbo

   Iwo l'a nwo t’a si nsin 

   Ma jek’oju tiwa 

   Ma jeki’awa omo Re 

   Sokun ni ainidi

   Iwo la gbekele

   Iwo ni ‘reti wa

   Ran wa lowo k’a le sin O 

   De opin emi wa. Amin

English »

Update Hymn