HYMN 718

8.7.8.7.4.7
Tune: Ma toju mi Jihovah Nla1. OLORUN Oluwa l'oba 

   Aye mbe niwaju Re

   Nibi t’awon angel nsin I 

   L’O gunwa ni ite Re 

   Eni Mimo

   Obangiji, On l'Oba.


2. Oba Ogo Ii Olorun 

   Sion royin Re k‘aye 

   lsra-eli ti igbani 

   Kede itan oto Re 

   Eni Mimo

   Mimo li oruko Re.


3. Li atijo, ni ‘gba ewu 

   T’awon ojise Re be

   O gbo gbe awon eniyan Re 

   N'nu eru won, O dahun 

   Eni Mimo

   Won ri n'tosi gba won p'e.


4. Awon l‘afun l’ofin mimo 

   Lat' inu awosanma

   Ilana mimo ti won ru 

   Mu ki O binu si won

   Eni Mimo

   Won kanu fun ese won.


5. Sugbon Baba won fiji won 

   Gba won tun safari Re

   O mura tan lati gba won

   O f‘ife gba won pada

   Eni Mimo

   Awa na nw’or'ofe Re.


6. Baba wa n’iyonu n'nu Kristi 

   Y‘o mu ileri Re se

   Wa, k‘a gbe ga, gbogbo'alaye 

   E wa soke mimo Re!

   Eni Mimo 

   E sin loke mimo Re. Amin

English »

Update Hymn