HYMN 719
L.M (FE 746)
"Kili emi of fun Oluwa” - Ps.116:12
1.  KIL’O tun ye wa loni yi
     Bi k’a jo k’a yo s‘Oluwa 
     T'o mu wa r’odun yi l’ayo 
     E ho, e ke halleluyah.
2.  Eyi daju niti wa pe
     Jesu Kristi wa larin wa
     O ni k’a f’okan wa bale 
     Baba ko ni jek’a yan ku.
3.  B’Oluwa ko ko ile na 
     Awon ti nko nsise lasan 
     B’Oluwa ko pa ilu mo 
 
     Oluso sa kan ji lasan.
4.  Gbogbo Enyin asiwaju 
     Tesiwaju n’ise Oluwa 
     Baba y‘o f’agbara wo nyin 
     Lati segun esu at’ese.
5.  Oluwa y'o dabobo wa 
     Olomo ko ni padanu
     Agan y'o towo re b’osun 
     Aboyun y'o bi l'abiye.  Amin
English »Update Hymn