HYMN 730

H.C 117 6s (FE 756)
"E mase beru won" - Deut. 1:29
“Orin yi wa fun akoko wahala lehin 
kiko we a o ka Psalm 14,144,191. 
Ohun Orin “Kristi k’ijoba Re de”



1.  MAIKIEL Olusegun 

     Yara sokale wa 

     Loni n'isegun re 

     Mase duro pe mo.


2.  lsegun re, baba
 
     O po ju t‘enia 

     Jehora Oba wa 

     Segun iku fun wa.


3.  Ogun aje gbona 

     Ogun oso gbona 

     Asahola-Hurah 

     Wa segun ota wa.


4.  Apejuba-Hujjah 

     Yawotah-Saharah 

     Enyin onida ina 

     Segun aje fun wa.


5.  Iyamma-Iyanna 

     Oba ‘Lewilese 

     Ajagorah-Hullah 

     P’agbara aje run.


6.  Enyin Kerubu orun 

     At‘enyin Serafu

     E nde fun iranwo 

     Awa t’aginju aiye.


7.  Emmanuel Baba 

     Olusegun iku 

     Oba aiku ni O 

     Yara wagba wa la.


8.  Ojira-Saro-Fa 

     Eli-Eli-Yaworah, 

     Oba ‘wimayehun 

     Wa se t’emi n’ire.


9.  Ogo ni fun Baba

     Ogo ni fun Omo,

     Ogo f‘Emi Mimo 

     Metalokan lailai.  Amin

English »

Update Hymn