HYMN 731

8.7.8.7.D
Tune: Baba wa orun awa de1. BABA orun, 'wo lo mu wa 

   D'ojo oni l‘alafia

   Pele I’O nto isise wa

   T’O si nf'iso Re so wa 

   ‘Wo Ore at’Amona wa

   A fe fi ope fun O 

   Ao se le yin O b'o ti ye 

   Fun ‘fe Re ti ki pada?


2. Ni gbogbo igba t’o koja 

   L’a nri anu gba lotun

   Itoju on iseun-ife

   Ko fi igba kan jin na

   Ife ati aba orun

   Mba wa gbe tosan-toru 

   Ibukun t’a ko le siro 

   Ntan imole s’ona wa.


3. N’nu ‘danwo nla l’a ti koja 

   Iji ‘ponju ti lu wa 

   Idamu ti sokun bo wa 

   Tobe t’a ko fi ri O 

   Sibe ife Re ko ko wa 

   Sibe n’nu banuje wa 

   Iranwo t’a nse f’ara wa 

   Nipa agbara Re ni.


4. Opo awon olufe wa

   Ti de opin ajo won 

   Ara, omo ati ore 

   Nwona lati pade wa 

   Nigbat’ ajo wa ba pari 

   Ti a si se alaisi

   Baba, mu wa la okun ja 

   Sinu mole ailopin. Amin

English »

Update Hymn