HYMN 733

t.C.M.S 90 D. 7s 6s (FE 759)
"E fi ibukun fun Olorun li egbegbe 
ani fun Oluwa, enyin ti o ti 
orisun Israeli wa" - Ps 68:261. EGBE Kerubu Seraf‘ 

   Egbe ogun orun

   Egbe awon Aposteli 

   Egbe ljo Mimo 

   Gbogbo won loke orun 

   Nyin O t‘osan, t‘oru 

   W'Olorun Metalokan 

   Oga Ogo julo.


2. Awa Egbe Serafu 

   Aiye nyin O, Baba 

   lfe Tire ni ki a se 

   Bi nwon ti nse lorun 

   Pelu wa b'a ti pejo 

   Je k’a le sin l’emi 

   Baba wa, jo sokale 

   F’Ogo Re han nihin.


3. Larin ainiye ibi

   To rogba yi w‘a ka 

   Larin ‘jamba on ‘ponju 

   To ja ni igboro wa

   Emi o f'ope fun O

   Tori Iwo da mi si

   Oba Afenife-re

   Ogo f'Oruko Re.


4. Gba Noah rubo ope 

   Wo f’osumare han 

   Majemu pe ikunmi 

   Ki yio bo aiye mo 

   Baba f’osumare han 

   N'irubo isin wa

   K‘a mase ri ibi mo 

   Jakejado le wa.


5. We lo d’Egbe yi sile 

   Se Egbe na logo 

   S’Amona at'Odi re 

   Larin danwo aiye 

   Baba Olodumare

   Wo lo npe ko yeni 

   Jek’o y‘Egbe yi kale 

   Nitori Omo Re. Amin

English »

Update Hymn