HYMN 740

C.M.S 113 O. t.H.C 235 S.M (FE 766)
“Awa ti ri irawo Re ni iha ila-orun"
 - Matt.2.21. IRAWO wo l'eyi? 

   Wo b’o ti daa to 

   Amona awon keferi 

   S’odo Oba ogo.


2. Wo awon amoye 

   Ti ila orun wa

   Nwon wa fi ori bale fun 

   Jesu Olubukun.


3. Imole ti Emi

   Ma sai tan n'ilu wa

   Fi ona han wa, ka le to 

   Emmaueli wa.


4. Gbogbo irun-male 

   Ati igba-male

   Ti ambo n'ile keferi 

   K’o yago fun Jesu.


5. Ki gbogbo abore,

   Ti mbe ni Afrika

   Je amoye li otito

   Ki nwon gb’ebo Jesu.


6. Baba Eleda wa

   Ti o fi Jesu han

   Awon Keferi igbani

   Fi han fun wa pelu. Amin

English »

Update Hymn