HYMN 744

C.M.S 132 O t.H.C. 14 L.M (FE 772)
“E lo, e ma ko oriIe-ede gbogbo”
 - Matt. 28:191. LO wasu ihinrere Mi,

   Mu gbogbo aiye gb‘oro Mi 

   Enit' o gb‘oro Mi y’o la 

   Enit‘ o ko yio segbe.


2. Emi o f‘oye nla han nyin 

   E o f'oro oto mi han

   Ni gbogbo ise ti mo se 

   Ni gbogbo ise t'e o se.


3. Lo wo arun, lo j'oku nde 

   F'oruko Mi l‘esu jade

   Ki Woli mi mase beru

   Bi Griki ati Ju nkegan!


4. Tan Serafu ka gbogb‘aiye 

   Mo wa lehin nyin de opin 

   Lowo Mi ni gbogbo ipa 

   Mo le pa, Mo si le gbala.


5. Ko gbogbo aiye l‘ase Mi, 

   Mo wa lehin nyin de opin 

   Lowo Mi ni gbogbo ipa 

   Mo le pa, Mo si le gbala.


6. Kerubu, Serafu aiye

   Ogo nla lo fi lo s‘orun 

   Nwon si mu de ile jinjin 

   lhin igoke Olorun. Amin

English »

Update Hymn