HYMN 749

C.M.S 519 D.S.M (FE 783)
"O seun, Iwo-odo rere ati olotito bo
sinu ayo Oluwa Re." - Matt.25:211. ‘RANSE Olorun seun 

   Simi n'nu lala re

   Iwo ti ja, o si segun 

   Bo s‘ayo Baba re

   Ohun na de loru 

   O dide lati gbo

   Ofa iku si wo l'ara 

   O subu ko beru.


2. Igbe ta loganjo

   Pade Olorun re 

   O ji,o ri Balogun re 

   N'nu adura on ‘gbagbo

   Okan re nde wiri 

   O bo amo sile

   Gbat’ile mo ago ara 

   Si sun sile l'oku.


3. Rora iku koja

   Lala at'ise tan

   Ojo ogun jaja pari
  
   Okan re r‘alafia 

   Omo-ogun Krist‘ o seun! 

   Ma korin ayo sa!

   Simi lodo Olugbala 

   Simi titi aiye. Amin

English »

Update Hymn