HYMN 750

S.M (FE 784) 1. O sun, ni Jesu wi

   Nigbati Lasaru

   Enit’o ku, ti a ti sin 

   T’a ti te s’ iboji.


2. Oku ojo merin 

   Sun ni, loju Jesu

   On l’Ajinde ati lye 
 
   Fun awon t’o gba gbo.


3. Ore Jesu ki ku 

   Nwon a ma parada 

   Kuro ni kokoro ile 

   S’ohun ti nfo l’oke.


4. Sun, ara, olufe 

   Jesu duro ti o

   Ma foiya, o ti seleri 

   Ajinde f’eni Re.


5. O fere gb’ohun na 

   Lat’oju orun re

   Ohun didun Jesu ti y’o 
 
   Pe o si ajinde.


6. A ko ni baraje

   Bi alanireti

   O d’owuro l'a o ki o 

   Pe o si ajinde.


7. Awa pelu y’o sun

   Li akoko tiwa

   A! k’ile mo ba gbogbo wa 

  L’ese Olugbala. Amin

English »

Update Hymn