HYMN 754

C.M (FE788)
“Ibukun ni fun oku ti o ku nipa ti 
Oluwa" - Ifi. 14:13
Tune: Itanna t’o bo gbe1. ALABUKUN l’awon oku 
 
  Nipa ti Oluwa 

  Kowe re be ni Emi wi 

  Se won nto won lehin.


2. Nwon simi ninu lala won 

   Kuro l’aginju yi

   Nwon nyo larin Egbe Mimo 

   Loke orun lohun.


3. Ayo won ko se f’enu so 

  Larin Egbe Ogo

  Jesu ti nwon ti gbekele 

  Si ti re won lekun.


4. Ainiye l’awon Kerubu 

  To y'ite Baba ka

  Seraf’ t’enikan ko le ka 

  Nwon nko Halleluyah!


5. Agbagba Merinlelogun 

   Eda ‘alaye Merin 

   Nwon y’ite Olugbala ka 

   Nwon nko Mimo Mimo.


6. Ewa ogo ‘be ti po to

   A ko le fenu so

  Didan l’awon ta se logo 

  Nwon nko orin Mose.


7. A f’ogo fun Baba l'oke 

   A f’ogo fun Omo

   A f’ogo fun Emi Mimo 

   Metalokan lailai. Amin

English »

Update Hymn