HYMN 761

O.t.H.C 164 C.M (FE 795)
“Ni kutukutu o Ii awo lara, o si dagba
soke, Ii asle a ke e lule o si ro" - Ps.90:61. ITANNA t'o bo gbe l’aso 

   T'o tutu yoyo be

   Gba ‘doje ba kan, a si ku

   A subu, a si ro.


2. Apere yi ye f'ara wa 

   B‘or' Olorun ti wi
 
   K‘omode at’agbalagba

   Mo ra won l‘eweko.


3. A! ma gbekele emi re, 

   Ma pe gba re n’tire

   Yika l’a nri doje iku

  O mbe ‘gberun lule.


4. Enyin t‘a dasi di oni 

   Laipe, emi y‘o pin
 
   Mura k'e si gbon akoko

   Kiko iku to de.


5. Koriko, b’o ku, ki ji mo

   E ku lati tun ye

   A! b'iku lo je lekun nko

   S’irora ailopin.


6. Oluwa, jek‘ a jipe Re 

   K‘a kuro n‘nu ese

   Gbat’ a lule bi koriko

   K’okan wa yo si O. Amin

English »

Update Hymn