HYMN 765

C.M.S 517 H.C 2 L.M (FE 799) 
“Eminkulojojumo”-I Kor.15:31


1. BI agogo ofo ti nlu

   Ti npe okan yi koja lo 

   K’olukuluku bi ra re 

   Mo ha se tan b’iku pe mi?


2. Ki nf’ohun ti mo fe sile 

   Ki nlo sibi ite ‘dajo

   Ki ngbohun Onidajo na 

   Ti y’o so ipo mi fun mi.


3. Ara mi ha gba b’O wipe 

   ‘Lo lodo Mi eni-egun 

   Sinu ina t’a ti pese

   Fun Esu ati ogun re.


4. Jesu, Oluwa jo gba mi

   Iwo ni mo gbeke mi le

   Ko mi ki nr’ona ewu yi

   Ko ni ki mba O gbe titi. Amin

English »

Update Hymn