HYMN 77

(FE 94)
“Ti Oluwa ni ile ati ekun re" - Ps. 24:11. T’OLUWA n’ile at’ekun re,

   Aiye at’ekun ‘nu re,

   O fi ‘di re sole lor‘okun

   Ati lori ‘san omi.

Egbe: Gb’ori soke

      Enyin ‘Iekun

      K'a gbe nyin soke

      K’Oba Ogo wole wa.


2. Tani yio g'ori oke yi lo

   Ori oke Oluwa

   Tani yio duro niwaju Re,

   Niwaju Oluwa wa.

Egbe: Gb’ori soke...


3. Enit'o ni owo mimo 

   T'o si ni aiya funfun,

   Ti ko gb'okan re s'oke s'asan

   Ti ko si bura etan.

Egbe: Gb’ori soke...


4. Awa n‘iran ti ns'aferi Re,

   Saferi Re Oluwa,

   Awa yio si ri ibukun gba,

   Lowo Olorun Jakob.

Egbe: Gb’ori soke...


5. A! Tani Oba Ogo yi?

  Ti ‘se Oba Ogo yi?

  Oluwa awon omo-ogun,

  On na ni Oba Ogo.

Egbe: Gb’ori soke... Amin

English »

Update Hymn