HYMN 78

8.7 (FE 95)
"Olorun si pe iyangbe ile ni ile" - Gen. 1:10
Tune: Ope lo ye f'Olugbala"1. T'OLORUN Oluwa nile

   Ati gbogbo ekun re,

   Aiye at'awon enia

   Ti O tedo sinu re.

Egbe: Awamaridi ni 'se Re,

      OLuwa omo-ogun

      Ogo Ogo ola at'agbara,

      Ni fun O, Metalokan.


2. Tani yio goke Oluwa

   Ati ibi Mimo Re

   Enit’o ni owo mimo

   TI aiyaa re si funfun.

Egbe: Awamaridi ni 'se...


3. Awon ti ko gbokan soke

   S'ohun asan aiye yi,

   Ti ko si je bura etan

   Yio ri ‘bukun Oluwa gba.

Egbe: Awamaridi ni 'se...


4. Eyi I’awon ti nsaferi

   Oju Olorun Jakobu,

   Awon to duro d'Oluwa

   Ni yio ri ‘bukun gba.

Egbe: Awamaridi ni 'se...


5. Gbori soke enu ona,

   Ka si tun gbe nyin soke

   Enyin l‘ekun aiyeraiye,

   K'Oba ogo le wole.

Egbe: Awamaridi ni 'se...


6. Tani Oba Ologo yi!

   Oluwa Omo Ogun

   Eni to I'agbara l‘ogun

   On ni Oba Ogo yi.

Egbe: Awamaridi ni 'se...


7. Gbori soke enu ona,

   K'Oba ogo le wole

   Tani Oba Ogo yi?

   Oluwa Omo Ogun.

Egbe: Awamaridi ni 'se... Amin

English »

Update Hymn