HYMN 788

C.M (FE 822)1. OGO OBA wa ti po to 

   Ti mbe l’oke orun, 

   Omo-kekere wo l’o le, 

   Korin ola ‘nla Re.


2. Ta l’o le rohin ipa Re 

   At’ore-ofe Re

   Ko s’enikan l’aiye l’orun 

   To mo titobi won.


3. Angeli t’o yi Oluwa ka

   Ko je so ‘tumo re

   Sugbon nwon npa ase re mo 

   Nwon si nkorin ‘yin Re.


4. Nje mo fe ma ba won korin 

   Ki nm’ore temi wa 

   Oga-Ogo ki y’o kegan 

   Ohun orin ewe.


5. Mura, okan at'o ahno mi, 

   Lati korin iyin 

   S’Olodumare Eleda

   Ayo aw’Angeli. Amin

English »

Update Hymn