HYMN 789

C.M. (FE 823)
"Olorun yio busi fun wa" - Ps. 67:71. IBUKUN ni fun agbara

   Ododo on Ogbon 

   At’Ore-ofe t‘o papo 

   S'Ise Igbala wa.


2. Baba wa j’eso-gi aije 

   Ogo Re si wo mi 

   Awa omo re si d’eru 

   Esu ati Iku.


3. Ope fun Baba t’o f'Omo 

   Re kansoso fun wa 

   Enit’O ku, k’awa le ye 

   Ka le d’om'Olorun.


4. Ofin Baba gbogbo t’a ru 

   L’Omo ti a pa mo

   O ku lori agbelebu 

   Nitori ese wa.


5. Wo! O Ji dide n‘iboji 

   O si goke r’orun 

   Nibe li O nf’ ltoye Re 

   Gba gbogb’ arufin la.


6. O gunwa lor’ite ogo 

   Pelu agbara nla

   O f’ewon ide ese ja 

   T'Esu ti fi de wa. 


7. O si tun mbo wa se ‘dajo

   Pelu ola-nla Re

   Y’o pe awon oku mimo 

   Jade pelu ayo.


8. Mba le duro l'ayo pelu 

   N’waju O n d‘dajo yi!

   Ki nsi korin irapada

   Pel‘ awon t'a gbala. Amin

English »

Update Hymn