HYMN 79

‘Duro de ileri Baba (FE 96)
Tune: Ile kan mbe to dara julo
Ise. 1:41. BABA Mimo jowo sunmo wa,

   Omo Mimo jowo sunmo wa,

   Emi Mimo jowo sunmo wa,

   A sunmo O, fi ‘bukun fun wa,

Egbe: Baba wa, Baba wa

      Edumare jowo bukun wa,

      Baba wa, Baba wa,

      Edumare jowo bukun wa.


2. Jehovah Jire wa ba wa pe,

   K‘O si ma gbe inu okan wa,

   Masai f‘oju anu Re wo wa,

   Ko si f‘ese Egbe wa mule.

Egbe: Baba wa, Baba wa...


3. Oluwa pese Emi Re fun wa,

   Ka wa le sin O titi d’opin

   Ko si ma samona Egbe wa,

   Ka le fi ‘joba Re s‘ere je

Egbe: Baba wa, Baba wa...


4. Pese fun gbogbo awon omo Egbe

   Pese ise f‘awon alairise,

   Mase jeki gbogbo wa rahun

   Masai fi ‘bukun Re kari wa.

Egbe: Baba wa, Baba wa...


5. Nigbat‘ a ba si f’aiye yi sile

   Ka wa je eni ‘tewogba

   K'awa sile ba Jesu gunwa,

   Niwaju ite Metalokan.

Egbe: Baba wa, Baba wa...


6. Nikehin k’a le gbo ohun ni,

   E wa enyin Alabukun fun

   Bo sinu ayo Oluwa Re,

   K’a le b’awon Angeli korin ‘yin.

Egbe: Baba wa, Baba wa... Amin

English »

Update Hymn