HYMN 790

C.M. (FE 824)
“E mu iyin Re Ii ogo" - Ps.66:21. GBOGBO talaka ti mo mo 

   Nwonti po n’iye to 

   Kini mba se f’Olorun mi 

   Fun gbogbo ebun Re?


2. Mo san j’awon elomi ni 

   T’Olorun se nke mi? 

   Awon ti nkiri, ti nsagbe 

   Lati ile de ‘le?


3. Alakisa omo melo 

   Ni mbe l'otutu yi? 

   Gbati a fi aso wo mi 

   Lat' ori d‘ese mi.


4. Gba t’awon mi se alairi 

   Ibi gb‘ori won le 

   Emi ni ile lati gbe

   Ati ‘bukun rere.


5. Gbat awon mi, ti nwon npuro 

   Ti njale, ti mbura

   Ni mo ti ko iberu Re

   Lati igba ewe mi.


6. Sa wo, bi oju rere Re

   S'emi nikan ti po

   Nje o ye ki nfe O pupo

   Ki nma sin O rere? Amin

English »

Update Hymn