HYMN 794

C.M.S 479. H.C 511 8.6
8.6.8 (FE 828)
"Nwon ti fo aso igunwa won, nwon 
si so nwon di funfun ninu eje 
odo-agutan” - Ifi.7:141. YIKA or’ite Olorun 

   Egberun ewe wa,

   Ewe t'a dari ese ji 

   Awon egbe mimo 

  Nkorin Ogo, ogo, ogo.


2. Wo! olukuluku won wo, 

   Aso ala mimo

   Ninu imole ailopin 

   At'ayo ti ki sa,

  Nkorin Ogo, ogo, ogo.


3. Kil‘o mu won de aiye na, 

   Orun t’o se mimo

   Nib’ alafia at’ayo

   Bi nwon ti se de ‘be? 

   Nkorin Ogo, ogo, ogo.


4. Nitori Jesu ta ‘je Re, 

   Lati k‘ese won Io;

   A ri won uinu eje na, 

  Nwon di mimo laulau, 

  Nkorin Ogo, ogo, ogo.


5. L‘aiye, nwon wa Olugbala 

   Nwon fe oruko Re, 

   Nisisiyi nwon r’oju Re, 

   Nwon wa niwaju Re, 

   Nkorin Ogo, ogo, ogo.


6. Orisun na ha nsan loni?

   Jesu, mu wa de be

   K‘a le ri awon mimo na 

   K'a si ba won yin O,

   Nkorin Ogo, ogo, ogo. Amin

English »

Update Hymn