HYMN 795

O.t.H. C. 289 C.M. (FE 829)
"E mase fe aiye" - 1John. 2:151. AWA fe ohun aiye yi 

   Nwon dara l‘oju wa 

   A fe k‘a duro pe titi 

   Laifi won sile lo.


2. Nitori kini a nse be? 

   Aiye kan wa loke 

   Nibe l'ese on buburu 

   Ati ewu ko si.


3. Aiye t’o wa loke orun

   Awa iba je mo

   Ayo, ife inu rere 

  Gbogbo re wa n’be.


4. Iku, o wa ni aiye yi 

   Ko si loke orun 

   Eniyan Olorun wa mbe 

   Ni aye ni aiku.


5. K’a ba ona ti Jesu lo

   Eyi t'O la fun wa

   Sibi rere, sibi simi

   S’ile Olorun wa. Amin

English »

Update Hymn