HYMN 803

(FE 838)
“Akanse orin fun Egbe Serafu
nipa A. K. Ajisafe” 
“Emi yio te o lorun li Oluwa wi" - Jer.31:14 1. BABA Olorisun ibukun gbogbo 

   Awa yin O fun ‘pade wa loni 

   Jowo f’orisun ibukun Re fun wa, 

   Orisun ‘bukun Re ti ki gbe lai,

   Olorun Abram, o d’owo Re, 

   Nitori Jesu masai gbo ebe wa.


2. Seri bukun Re s'ori gbogbo egbe 

   At’lgbimo l‘okunrin l‘obinrin

   Egbe Akorin ati gbogb‘ osise

   To mbe ninu Egbe Serafu yi; 

   Olorun Aaron, o dowo Re

   Di Egbe Serafu l'amure ododo.


3. Jo ma jeki fitila Egbe yi ku, 

   Jo mase je k'ota le ri gbe se

   Jo tun gbogbo ibaje inu re se,

   Je k' o gbile n'nu ‘fe on ‘wa mimo 

   'Wo Oba Sion, o dowo Re, 

   Jo mo je k‘iyo Egbe wa yi d’obu.


4. Bukun f'awon ara ati ore wa, 

   Omo Egbe at'awon oworan 

   Je ko ro wa; je k’ile roju fun wa

   K'a mase tori ara wa pose 

   Jehovah Salem, o dowo Re, 

   Mu ki ‘paiya lo k‘alafia po si.


5. Siju anu Re wo gbogbo Egbe wa, 

   Dawo pasan ibinu Re duro

   Darij' awon ota at’elegan wa, 

   Mu ota at'ija kuro fun wa, 

   Jehovah Rufi, o dowo Re, 

   S’awotan arun to mba ilu wa ja.


6. Baba, ma f'ebi kehin ayo fun wa

   K’a mase f’akisa pari aso,

   Ma je ka f’arun pari ara lile 

   Ma je ki awa ku sowo Esu 

   Olorun Haggar, o dowo Re, 

   Pese itura fun wa li aiye wa.


7. Jowo f‘ike Re ke awon alaisan 

   F‘adun si f’awon t'aiye won koro,

   Fi ire kun gbogbo awon ti ebi npa;

   Jo ma je k’awon omo wa yanku, 

   Jehovah Nissi, o dowo Re 

   Masai j'Opagun fun gbogb‘awon Tire.


8. ‘Wo lo mu wa wa laye titi d‘oni

   Je k'idasi wa je fun Ogo Re, 

   Lowo ewu at‘ipalara gbogbo 

   Jesu, masai fi iso re so wa, 

   Oyigiyigi, o dowo Re,

   Pa mi mo ki nmase gb'ojo olojo lo.


9. Lojo ti ao se idajo aiye, 

   T’awon Angeli y‘o wa kore fun O,

   Gba wa, Jesu, gba wa ni ojo nla la

   K’a wa le je ninu ire nla na, 

   Krist’ olugbala, o dodo Re, 

   Ma je ki ntase ibukun rere na. Amin

English »

Update Hymn