HYMN 805

C.M. (FE 840)
"Oluwa li olupamo Re” - Ps.121:5 
Tune: Emi Ba l’egberun Ahon1. OLUPAMO gbogbo eda, 

   Oba Asekan-maku 

   Awa fi malu ete wa 

  Rubo ope si O.


2. T’Omode at’agba dupe 

   F’abo Re loni wa 

   Fun ike ati ise Re 

   Lori wa lat‘esi.


3. E bu s‘ayo Omo Ogun 

   Ati gbogbo egbe 

   Ajodun t’oni t'o ba wa 

   Lorile alaye.


4. Eleru, Niyi, a be O

   Se wa l’enia Re

   K’a mase pada lodo Re 

   K’a le sin O dopin.


5. Awa si mbebe siwaju 

   Nin'odun t'a wa yi

   Fi ohun rere kari wa 

   S’aiye wa ni rere.


6. Oba amona gbogb’eda 

   S'amona wa dopin

   Ma jek’ esu ba wa d'egbon 

   Ma jek’ a padanu.


7. B’a ti njosin, t‘a si nyin O 

   L’aginju aiye yi 

   Se wa ye k’a tun le yin O 

   Loke orun pelu. Amin

English »

Update Hymn