HYMN 814

H.C 148 S.M (FE 849) 
“Emi li ona ati otito ati iye" - Matt.14:61. JESU, Oto Ona 

   Mole ni t’o daju

   Gbe ese mi ailokun ro, 

   To mi s’ona tito.


2. Ogbon at' Amona 

   Oludamoran mi 

   Ma je ki nfi O sile lai 

   Tabi ki nsako lo.


3. Mo gb‘oju mi soke 

   Wo O, Od‘agutan

   Ki O ba le la mi l‘oye 

   K'oju mase ti mi.


4. Nki o gba oran mi 

   Kuro ii owo Re

   Ngo simi le ‘fe rapada 

   Ngo ro m‘agbelebu.


5. Ko mi ki nmo adun 

   Ati gbekele O

   Jo, Oluwa, mase ya mi 

   Sugbon fe mi d’opin.


6. Mu mi la ‘danwo ja 

   De ‘le alafia;

   Si ko mi li orin titun 

   Gba mo ba di pipe.


7. Jeki nle dabi Re

   Ki nto se alaisi

   Fi ese mi mule sinsin 

   Ki ndagba n’nu ife.


8. Jeki nj‘eleri Re

  Gbat’ese ba run tan

  Gba okan mi ailabawon

  K’O si mu mi d’orun. Amin

English »

Update Hymn