HYMN 815

(FE 851)
"Gba mi kuro li enu kiniun ni”
 - Ps.22:21
Tune: K & S 1871. OLORUN Alagbara nla

   T’O p’ara Egypt run

   L’eti okun nijokini 

   P'agbara Ota mi run.

Egbe: Jowo gbe mi leke 

     Ma jek'ota bori mi

     Segun, gbogbo ota fun mi,

     Gbe mi leke ‘danwo.


2. Jesu, loni mo kepe O, 

   Baba mi gbo temi

   Segun gbogbo' ogun ti mo ri

Egbe: Mase jeki nseku

     Mu ki Ifoiya mi lo

     F'okan mi bale lat'oni 

     K’ota ma le mi mo.


3. Jesu Olori Egbe wa, 

   Wo ni mo gbekele 

   Lai, ma jeki oju ti mi 

   Pese fun aini mi.

Egbe: Baba, mo sa di O 

     S’aiye mi ni rere

     Ki ikolu tabi ikolo 

     Mase subu Iu mi. Amin

English »

Update Hymn