HYMN 816

D. 7s (FE 852)
Tune: Bugbe Re ti Lewa To1. JESU Iwo Oba mi 

   Iwo ni mo gbekele 

   L’aiye yi nko l’enikan 

   Lehin Re ‘Wo Oba mi 

   Torina gbe mi leke 

   Gbe mi bori ota mi

   Ki nlayo ki nni segun 

   L’ojo aiye mi gbogbo.


2. Fun mi ni ore-ofe 
 
   Se mi ye l‘eni tire 

   K’ota mase le mi ba 

   S’aiye mi d'ire fun mi 

   Wo t'o so aiye Esther 

   Di rere fun nigbani 

   Wa s’aiye mi di rere 

   Jeki im‘ota le d’ofo.


3. Gbe mi leke, mo fe be 

   We Oba agbara gbogbo 

   Ipa ota ko to nkan 

   Niwaju agbara Re 

   Torina, Eleda mi

   Pa agbara ota run 

   K’ota ma yo mi lenu 

   Gbe mi leke isoro.


4. Wo ti wa k‘aiye to wa 

   Wo ti wa k‘orun to wa 

   Torina Jesu temi

   Jek'ola Re han fun mi 

   Tobe t’emi na yio ri

   Ogo Re, agbara Re 

   T'aiye yio si ri pelu

   Pe ‘Wo l'agbara gbogbo.


5. Fi Ola Re yi mi ka

   Fi Ogo Re yio mi ka 

   K‘agbara Re s’abo mi 

   K'oruko Re s’abo mi 

   Tobe ti ngo di ti Re 

   K‘aiye ma le ri di mi 

   K‘owo esu ma te mi 

   Tobe k’aiye mi I'aiyo.


6. Gba mo ba si de orun 

   Fun mi ni ipo lodo Re 

   Ki nj’eni owo ‘tun Re 

   Ki nye ni ori ite Re 

   Gbana l'ayo ni y'o kun 

   Nin’ ogo ti ko l’opin 

   Ninu ayo ti ki tan

   Ninu ola ti ki sa. Amin

English »

Update Hymn