HYMN 82

(FE 99)
“E fi ogo ati agbara fun Oluwa” - Ps. 29:11. IJO Kerubu a de, lati iyin Baba,

   Gbogho agbaiye e wa o,

   ka jo yin Baba.


2. lje Serafu a de, lati yin Baba,

   Tewe-tagba e wa o, kajo yin Baba.


3. lgun mererin e wa, ka lo yin Baba

   Kerubu pelu Serafu, awa nyin Baba.


4. Tomode tagba, e wa fi 'yin fun Baba

   Kerubu pelu Serafu, awa nyin Baba.


5. Jesu Olugbala, a de, lati yin Baba

   Jowo se ‘ranti Kerubu, 

   pe wa ni Tire.


6. Jesu Olugbala ko wa, 

   Jowo ko wa lo,

   Odo Baba wa loke, 

   Jowo ko wa lo.


7. Jesu Olugbala, o se, o ko

   Igbekun t'esu di sile, ko

   je k'awa gbe.


8. Enyin obinrin, e roju,

   e roju e ma bohun mo,

   Gbogbo eni dabi Hannah

   Baba o gbo tire.


9. Baba ranti arugbo, to wa ninu wa,

   K'ebi ale mapa won, jowo ranti won.


10. Emi Mimo wa, jowo fi han ni,

    Oro Mimo Bibeli, jowo fi han ni. Amin

English »

Update Hymn