HYMN 820

Tune: Jesu ni Balogun oko1. EMI l‘Olorun ni Baba 

   Iberu ko si fun mi

   B’o ti wu k'ota k’o gbogun 

   Ti Jesu ni yio bori 

   On l'ore ti ki tan ni

   Ko ni fi mi sile dandan

   Bo ti wu kiji ko le to 

   Yio mu mi gun s’ebute.


2. B’ojo nro t’orun nran pelu 

   B’ile nmi t‘oke si nyi 

   B’ara nsan b'ina njo kikan 

   Emi ko je se Jesu

   On l’Olugbala aiye 

   Boya opo eda ko mo 

   On ni yio ji wa dide 

   L’ojo ‘dajo ikehin.


3. Okan mi bale laiye mi 

   Mo l’Olorun ni Baba 

   Ko s’ohun bi to le se mi 

   Nipa eje omo Re

   Mo wa si bi orisun na 

   Jo we mi Olugbala mi 

   Mase je ki nsako kuro 

   Fa mi jeje sodo Re.


4. Di mi mu, di mi mu sinsin 

   ‘Nu oko gbala Seraf

   Mase je k’eranko enia
  
   Ba ise owo mi je

   Olorun Orimolade

   Lo d’Egbe Serafu s’ile

   Mo juba Olorun Re o 

   K'ona la f’adura mi. Amin


   

English »

Update Hymn