HYMN 827

t.H.C 6s 8s (FE 864)
“Oluwa si wi fun Mose pe, Emi li
eniti o wa" - Eks. 3:14 
Tune: E fun ‘pe na kikan1. MOSE Orimolade 

   Ni Oluko wa, 

   Olorun ran s'aiye 

   Lati d'egbe yi sile.

Egbe: Kerubu, Serafu l’o so)

     Oruko Egbe na.) -2ce


2. Olorun Tunolase 

   Ran Emi re si wa, 

   Ka mase se aseti 

   Ninu adura wa.

Egbe: Metalokan jo gbo tiwa)
 
      Fun wa n'ida Emi) - 2ce


3. Ma je k'esu tan wa,

   Lati se Tunolase

   Ka ma d'eni egbe

   Ni ojo ikehin.

Egbe: Metalokan jo gbo tiwa)

     Fun wa n'ida Emi) - 2ce


4. Lonakona t’ota,

   Ba ngbogun re si wa; 

   Baba Olusegun, 

   Segun logan fun wa.

Egbe: Oluwa Olorun omo gun) 

      Ma jek’ oju ti wa) - 2ce


5. Gbogbo eyin te duro 

   Lati je omo Mose 

   Olupilese IYE

   Yio di nyin mu dopin.

Egbe: Om'Alade Alafia)

      F'alafia fun wa.) - 2ce


6. A nlo si ile wa, 

   F‘ogun orun yi wa ka 

   Ki gbogbo ibi aiye 

   Ma le se wa nibi.

Egeb: P‘Aje, Oso Sonponna run) 

      F'awa omo Jesu) - 2ce


7. Baba Aladura

   Ti Baba gbe dide 

   K‘Olorun ran lowo 

   Ko gbowo re soke.

Egbe: Edumare, jo gbo tire) 

     B'o ti gbo ti Mose) - 2ce. Amin
 

English »

Update Hymn