HYMN 830

H.C. 492 7.6.8.6 (FE 867)
“Ko eko ti emi, nitori oninu tite ati 
oninu tutu Ii emi" - Matt. 11:291. MO fe ki ndabi Jesu 

   Ninu iwa pele

   Ko s’enit‘o gboro binu 

   Lenu Re lekan ri.


2. Mo fe ki ndabi Jesu 

   L’adura ‘gbagbogbo 

   L’ori oke ni On nikan 

   Lo pade Baba Re.


3. Mo fe ki ndabi Jesu 

   Emi ko ri ka pe

   Bi nwon ti korira Re to 

   O s’enikan n’ibi.


4. Mo fe ki ndabi Jesu 

   Ninu ise rere
  
   K’a le wi nipa temi pe 

   O se ‘won t’o le se.


5. Mo fe ki ndabi Jesu 

   T’o f’iyonu wipe

   Jeki omode wa sodo Mi 

   Mo fe je ipe Re.


6. Sugbon nko dabi Jesu

   O si han gbangba be 

   Jesu fun mi l’ore-ofe 

   Se mi ki ndabi Re. Amin

English »

Update Hymn