HYMN 835

T. c.m.s 385 c.c. 25 p.m (FE 872)
Ohun: Gbekele Olurun Re
“Oluwa ni mo gbeke mi le” - Ps. 11:11. GBOGBO Egbe Serafu 

   Foriti, e foriti 

   Ma je k’o re gbogbo nyin 

   E foriti

   Ninu irin-ajo re 

   Efufu lile le ja

   Ja fun ‘se re ma beru 

   Sa foriti.


2. Kerubu pelu Seraf 

   Foriti, e foriti 

   Awon Woli isaju 

   Nwon foriti

   Mura si ‘se ma w’ehin 

   Baba y'o gb'adura re 

   E foriti iponju

   Sa foriti.


3. Egun le wa lona 

   Foriti, e foriti

   W'o oke sile ‘bukun ni 

   E foriti

   Ranti oro to nwipe 

   E o fi iye goke 

   Lagbara Metalokan

   A ogb’ade. Amin

English »

Update Hymn