HYMN 839

(FE 876)
Tune: C.M.S 303 10s1. OJU ko ti ri, eti ko ti gbo

   Ese t‘OlugbaIa pa f’enia Re 

   Awon ti O feran ti nwon feran Re 

   Ti nwon nfi ayo sin ninu ile Re.


2. B‘Orun ti dun to ko si‘eni le mo 

   Ayo re ko ti la s'okan eda

   Bi ijoba aiye ba lewa to yi 

   Bawo n’ijoba Olorun yio ti ri?


3. Ilu ail'ese ti ko si iku 

   Nibiti a ki pe ‘O digbose

   Ti ko si ipinya ti ko si ekun 

   Ibiti Jesu joba yio ti layo to.


4. lpade pelu awon to ti lo

   Baba t‘on t'omo oko t‘on t‘aya 

   Ore at’ojulumo t’o ti saju

   A! b’ijoba Olorun yio ti dun to.


5. Pelu awon mimo lati ma ko

   Orin Mose ati t‘Od-agutan

   Nibiti ko si aniyan fun ara

   Ti jesu gbe nsike wa yio ti dun to.


6. Ki npadanu aiye on oro re

   K‘ese mi le te ilu ogo yi

   Nigba mo ba nrin ita wura l'oke 

   Ngo gbagbe gbogbo iya ti mo ti je. Amin

English »

Update Hymn