HYMN 84

(FE 101)
"Emi o ma fi ibukun fun Oluwa nigbagbogbo,
iyin Re yio ma wa li eni mi titi" - Ps. 34:11. ENYIN Angeli to wa l‘orun

   E fi iyin fun Baba,

   F‘Egbe to da sile laiye

   Fun igbala emi,

   O ye ki inu wa ko dun

   Ki awa ki o si ma yo!

   Fun iranti lku Jesu

   Lori Agbelebu.

Egbe: A pa lase I’agbala orun

      Pe k’Egbe yi ma bi si

      A pa lase I'agbala orun

      Pe O si ma re si;

      Titi gbogbo ifoju okan

      Yio fi tan laiye

      T’iku Jesu Oluwa wa,

      Ko ni je asan mo.


2. Kerubu ati Serafu

   E fi iyin fun Baba

   Ti o da Egbe yi sile,

   Pe k’a le ri igbala,

   “Torina, e je k‘a mura

   Lati sare ije yi,

   Bi a ba foriti d’opin

   lye y’o je ti wa.

Egbe: A pa lase...


3. Gbogbo ise wa ti a nse,

   Gbogbo iwa ti a nhu,

   Gbogbo oro wa ti a nso,

   E je k‘a ma sora;

   Nitori Oluwa yio mu,

   Gbogbo ‘se wa si ‘dajo

   Ati gbogbo ohun ‘koko

   Ire tabi ibi.

Egbe: A pa lase...


4. Awa ni imole aiye

   Lati le okunkun lo,

   llu ta te sori oke

   A ko le fara sin;

   Awa si ni iyo aiye

   Ti a o mu aiye dun

   Sugbon b’iyo ba di obu,

   Bawo ni yio se dun?

Egbe: A pa lase...


5. Ope lo ye Olugbala,

   Fun ife to ni si wa,

   Ti o pe wa si Egbe yi,

   Oko ‘gbala ‘kehin

   Ogo, ola at’agbara

   Ola nla at‘ipa

   Ni fun Baba, Omo, Emi

   Metalokan lailai.

Egbe: A pa lase... Amin

English »

Update Hymn