HYMN 844

C.M.S 478, H.C C.M (FE 881) 
“Nitori ibi hiha Ii enu ona na"
- Matt. 7:141. ONA kan l’o ntoka s’orun 

   Isina ni ‘yoku

   Hiha si l’ojuona na 

   Awon Kristian l’o fe.


2. Lat’ aiye, o lo tarata 

   O si la ewu lo

   Awon ti nfi igboya rin 

   Y’o d’orun nikehin.


3. Awon ewe y’o ha ti se 

   Le la ewu yija?

   Tori idekun pe l’ona 

   F’awon odomode.


4. Gbigboro l‘ona t'opo nrin 

   O si teju pelu

   Mo si mo pe lati dese

   Ni nwon se nrin nibe.


5. Sugbon k’ese mi ma ba ye 

   Ki nma si sako lo

   Oluwa, jo s’Oluto mi 

   Emi ki o sina.


6. Nje mo le lo l’aisifoya 

   Ki ngbekel’ oro Re

   Apa Re y‘o s’agutan Re 

   Y‘o si ko won de ‘le.


7. Beni ngo la ewu yi ja 

   Nipa itoju Re

   Ngo tejumo ‘bode orun 

   Titi ngo fi wole. Amin

English »

Update Hymn