HYMN 847

H.C. 401 8.8.8.8.8.8 (FE 888) 
“Nwon simi ninu lala won” - Ifi.14:131. AWON mimo, lala pari 

  Nwon ti ja, nwon si ti segun 

  Nwon ko fe ohun ija mo 

  Nwon da won ‘Ie l’ese Jesu: 

  A! enyin eni ibukun

  Isimi nyin ti daju to!


2. Awon mimo, irin pari 

  Nwon ko tun sure ije mo, 

  Are at’ isubu d’opin,

  Are on eru ko si mo

  A! enyin eni ibukun 

  Isimi yin ha ti dun to!


3. Awon mimo, ajo pari 

  Nwon ti gun s’ile ibukun 

  Iji ko deruba won mo 

  Igbi omi ko n’ipa mo

  A! enyin eni ibukun

  E nsimi n’ib’ alafia.


4. Awon mimo, oku won sun 

  Ninu ile, awon nsona

  Titi nwon yio fi jinde

  Lati fi ayo goke lo

  A! eni ‘bukun, e korin 

  Oluwa at’Oba nyin mbo.


5. Olorun won, Wo l’ankepe 

   Jesu, bebe fun wa l’oke

   Emi Mimo, Oluto wa 

   F’ore-ofe fun wa d’opin 

   K’a le b’awon mimo simi 

   Ni Paradise pelu Re. Amin

English »

Update Hymn