HYMN 851

(FE 893)
Tune: Baba Jo Ranti mi1. A dupe lowo Oluwa

  To da wa si d‘oni

  Ti ko f’okan adaba Re 

  Le eranko lowo

  Iku ati Esu gbogun, 

  Sibe ko ta wa nu

  Ogo f'Oba Mimo julo 

  Kabiyesi Oba.


2. Melomelo lore, Re 

   Oba awon Oba

   Ti pamo ati iso Re, 

   Tabi lsegun ota 

   Loju ala, loju aiye, 

  Tabi ti pese Re 

  Iwosan lona iyanu, 

  A dupe Oluwa.


3. Owo wa ko to dupe, 

   Aso ko to dupe

   Ko s’ohun ta le fi dupe 

   Bikose ohun wa

   Ka f’okan wa fun Kristi 

   Lati aiye yi lo

   Ka yo orun le je ti wa, 

   Ti Kristi ti seleri.


4. Bani owo lainiye,

   B’a ni ‘le lainiye

   Ba so wa po bi ti Lilly 

   B'omo po lo titi

   Ba rope ayo wa tikun, 

   Rara ko iti kun

   Oku bako ti seleri 

   Eru ni n‘eru wa.


5. Kilo tun ba o leru,

   Ti Jesu ko le se

   Damuso lo wa niwaju re, 

   Pe Jesu fun ran ‘wo 

   Peteru pe fun ranlowo, 

   Ko je ko ri somi 

   Hezekiah Oba tun pe,

   O segun Keferi.


6. Won to feje ti Kristi, 

   Yio pinu lokan won 

   Lati yago fun Lusifa 

   A t'omo ogun re

   Ija, Ibinu, Arakan 

   Ati iwa Eri 

  Ainife ati ailanu, 

  Ko won sile loni.


7. A dupe lowo Oluwa 

  Oba awon Oba

  Atobiju, Eni ‘yanu 

  Olugbala Eda 

  Eleda, Olojo oni,

  A juba Oko Re

  Ore Re poju kika lo, 

  A dupe Oluwa. Amin

English »

Update Hymn