HYMN 864

SM
"Enyin o gba agbara nigbati Emi
Mimo ba ba le nyin” - Ise. 1:81. EMI alagbara

   Wa joko ninu mi

   Ki o si fun wa n’idande 

   Low’ eru on ese.


2. Emi lmarale

   Gbe arun ese lo

   Emi iwa-Mimo pipe 

   Emi ife pipe.


3. M’ojo na yara de

   Ti a run ese mi

   T’ohun atijo y’o koja 

   T’ohun gbogbo d’otun.


4. Ese abinibi

   Pare li okan mi

   Wole, ki O si le jade

   Gba gbogbo okan mi kan.


5. Oluwa mo fe ni 

   Eri pe mo nse ‘re

   Gege bi ‘fe at‘oro Re 

   B’o ti to loju Re.


6. Nko fe ipo giga 

   Sa fi eyi ke mi

   Nigbakugba t’o ba si ya 

   Gba mi s’orun rere. Amin

English »

Update Hymn